Ìfẹ́ gbígboná tí Tuface ní sí asofin Natasha kó ẹbí akọrin náà sí hílàhílo

Phenomenal
Phenomenal
Tuface pelu Natasha

Ìfẹ́ gbígboná tí Tuface ní sí asofin Natasha kó ẹbí akọrin náà sí hílàhílo

Bi o tile je pe nnkan ayo ni ife je, to maa n mu idunnu wo ile, ife eyi ti akorin igbalode pataku, Tuface Idibia, ni si asofin kan ni Ipinle Edo, Natasha Osawaru, ti da hilahilo sile ninu ebi re o.

Leyin ti Tuface kede pe igbeyawo oun pelu aya re tele, Annie Idibia, ti fori sanpon, o kede pe oun ti ri aayo okan miran.

Eyi lo je Natasha, to je omo olowo kan ni Ipinle Edo, iyen awon idile Igbinedion, to si tun je oloselu to ri jaje debi pe onarebu ni.

Awada ni awon eniyan koko pe e: sugbon Tuface ti gbe oro ife naa leri gidi.

Ojoojumo lo n korin rere ki Natasha, to n di mo o gbagi gbagi, to si n fi ete re lanu bi aja se n fi omi lanu.

Koda, o ti fun Natasha ni oruka a-maa-fera, iyen engagement ring, bayii.

Eyi ti da awuyewuye nla sile.

Awon kan n so kobakungbe oro si Tuface, to fi mo asoro lori mohunmaworan TVC, iyen Morayo Afolabi-Brown.

Won ni iwa buruku ni Tuface n hu bo se da Annie nu, to si n fi ife Natasha la a loju.

Oro naa n dun awon kan tori won ni inu ailera kan ni Annie wa.

Bi awon kan ti wa n so pe ko si ohun to buru ninu ohun ti Tuface n se ni idile re tun n ro wuduwudu bi omi eyin to wa lori ina.

Iya Tuface gan-an, iyen Iyaafin Rose Idibia, ti gbena woju Natasha tori o nigbagbo pe o ti se efo fun omo oun je ni.

O ni iwa ti omo oun n hu kii se oju lasan, tori a kii ni igi loko ka ma mo eso re.

O wa ke pe awon omo Naijiria ki won gba oun lowo Natasha o.

Bakan naa, ebi akorin naa ti ko leta gbajare si awon agbofinro, ti won si so pe awon ko mo ibi ti Tuface wa bayii.

Sugbon bi awuyewuye se n lo naa, Tuface ko jade sita, to si je pe fidio bi oun ati Natasha se n fi ife sere ni a n ri lojoojumo.

Ohun ti eyin naa ba wa ro lori oro yii, e je ka mo o.

TAGGED: ,
Share this Article