Akeem Lasisi
Opo omo Naijiria ni won n se adura emi gigun pelu alaafia fun ogbontarigi onise okowo, Otunba (Dokita) Mike Adenuga, o, latari oore nla to n se fun ilu ati omoniyan.
Won n so o ni gbolohun pe ogun odun lonii, gboin ni t’oke, oke gbon-in gbon-in; ti won si n ko o lorin pe akalamogbo kii pa odun je, ati pe a kii ba okunrun eye lori ite: piri ni olongo ji.
Eyi waye leyin ti awon alaheso ati ika eniyan kan gbe iroyin iro kan jade lose to lo, ti won ni lapalapa ti ku.
Ka ma paro, ka ma seke, eyi da ipaya nla sile kaakiri agbaye, tori ipa pataki ti Adenuga n ko ni duniyan.
Sugbon, aseyinwa aseyinbo, aye ri i pe iro funfun balau ni awon alaheso n so.
Oga oniroyin pataki, Alagba Dele Momodu, eni to je alase OVATION magazine, lo tete ta omo Naijiria lolobo pe Adeniga wa laye, o wa laaye, to si wa kanpe ni ile ola nla Banana Island re, ni ilu Eko.
Adura IROYIN OWURO ni pe Olorun yoo tubo lora emi opomulero mo Yoruba naa.