È̩ẹ̀mẹta ọ̀tọ̀tọ̀ ni mo dákú nínú ọdún 2024 – Tunde Bakare

Phenomenal
Phenomenal
Bakare

Bola Afolabi

O ni, ‘2024 ni odun-n-ba-ku mi’

 

Ase orin eni Olorun ko pa lo ye ki gbajugbaja ojise Olorun, Pasito Tunde Bakare, o maa ko!

Olorun Oba nla lo ko o yo ni odun 2024.

Logbologbo fi i debi wi pe eemeta ototo lo daku laarin odun naa, nigba to je eni odun mokandinlaadorin, iyen 69 years.

Sugbon niwon igba to je pe eni Olorun ko pa ko ku, iku ye lori alagba naa, to si je pe orin iye lo n ko di oni.

Funra Pasito Bakare lo so oro yii ni Satide bii meji seyin, nigba to n se iwaasu nibi ayeye ojo ibi ogota odun ti agba oniroyin, Ogbeni Ademola Oni, eni to ti fi igba kan je adari iwe iroyin THE PUNCH.

Nibi ayeye naa to waye ni OPIC Events Centre ni Isheri, ni Ipinle Ogun, Pasito Bakare ni bi oun se darapo mo Oni lati baa dupe fun Olorun, oun naa n dupe lori ara oun ni.

O ni to ba je pe nnkan bowo sori fun oun ni 2024 ni, oun ko ni wa laye lati ba olojo ibi naa se ajoyo.

Lara awon asiko ti mimi naa mi ojise Olorun naa ni asiko to lo si ilu oyinbo, to subu lule.

O ni bakan naa, oun wa ni ipade kan ni Naijiria lojo kan, ti oun si n subu lo sile, ki awon to wa nibe to suuru bo oun, ti Olorun si yo oun leyin-o-reyin.

Pasito Bakare ni, “2024 yen ni odun-n-baku mi!”

Ninu oro isiri to so, Pasito Bakare se apejuwe olojoobi Oni gege bii alakikanju atio alseyori oniroyin.

Bakan naa, o ni eni to ni otito inu ni, to si maa n fi otito se gbogbo ohun to ba n se.

O fi kun un pe ni soosi awon, nibi ti Oni naa ti je omo ijo, oun kii ni ipaya kankan ti oun ba fi ise ran an.

Sugbon sa o, Bakare gba Oni nimoran pe ko ma feyin ti nitori pe o ti di eni ogota odun o.

O ni oun gan-an ti oun ti le ni aadorin, oun si n sise laiweyin ni.

O ni ohun to se pataki ni ki eniyan maa fun ara re niisinmi loore-koore; ki okun le maa po si fun oluware .

Opo eniyan lo pejo ti won ba Oni se ajoyo naa.

Lara won ni Minisita fun Eto Irinna tele, Alagba Rotimi Amaechi; Olota ti ilu Ota, Ojogbon Oba Adeyemi Lanlegbe; Alaga Media Solution ati High Impact Resort, Omooba Yanju Lipede; Oga Agbatele ni ile ise Punch Nigeria Limited tele, nibi ti Oni ti sise fun opo odun, Ogbeni Ademola Osinubi; ati Oludari ni Punch bayii, Ogbeni Adeyeye Joseph.

Opo awon oniroyin, to fi mo Komisanna Oro Iroyin ni Ipinle Ondo tele, Alagba Kayode Akinmade; Olubadamoran ati Akowe Oro Iroyin fun Gomina Babajide Sanwo-Olu, Alagba Gboyega Akosile; pelu Oga Agba ni ile ise iwe iroyin Telegraph, Ogbeni Ayodele Aminu, lo wa nibe lati ye Oni si.

Share this Article
Leave a comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *