Nigba ti Yoruba so pe oku lo n jebi, ase won mo ohun ti won n wi.
Abi bawo ni a se fe wo oro Aare Ologun nigba kan, Ogagun Ibrahim Babangida; ati oloogbe Sanni Abacha, ti oun naa figba kan je Aare Onibon?
Eyi da lori ibo June 12, 1993, ti ijoba won fagile, leyin ti oloogbe MKO Abiola wole, ti o na alabadije re, iyen Mohammed Tofa, nile loko bi eni lu baara.
Leyin opo odun ti Babangida ti n fenu meji soro lori ibo naa, o ti wa kede pe o daju saka pe Abiola lo jawe olubori.
Ko pin sibe o, o ni oun ko ni oun fagi le ibo naa. O ni Abacha ni, bo tile je pe bii ipo keta ni Abacha wa si ninu ijoba naa.
Inu iwe itan igbesi aye re, to pe akole re ni A JOURNEY IN SERVICE, to sese gbe jade lo ti so eyi.
Idi niyi ti opo eniyan fi so pe to ba di oro ogbon ewe, ka maa se bii Maradona, Babangida ni Babangida yoo maa je.
Niwon igba to je pe oku nii jebi, ti ko le dide soro ti enu re mo, bawo ni a se fe mo okodoro oro bayii?
Eyi tumo si pe ko si bi a se se efo ebolo ko ma run ti ayan.
Nje Babangida ko wa ti fi ogbon ewe ti o fi gba apeje Maradona han Abacha to wa ninu koto bi?
Sugbon sa o, opo omo Naijiria ni ko gba Babangida gbo.
Lona kinni, won ni ko si eni kan ti ko mo pe Abiola lo wole.
Lona keji, won ni awawi asan ni Babngida n se bayii, tori ipinnu oun ati awon emewa re lati da June 12 nu se akoba alainiye ba oselu, oro aje ati irepo Naijiria.
Erongba opo eniyan bayii ni pe ijoba Tinubu yoo se oun to to, nipa fifi oruko Abiola mo ti awon olori orile-ede yii tele, ki ebi re naa si maa je anfaani ti awon yoku n je.