Ikú àlùmuntù:Agbako pẹ̀yin dá gẹ́gẹ́ bíi Olofaana,Ogunjinmi Ajagajígì-oògùn ati Sisi Quadri tí wọ́n wọlẹ̀ sùn ní 2024

Phenomenal
Phenomenal
Olumo

Bola Afolabi

Iku alumuntu:Agbako peyin da gege bii Olofaana,Ogunjinmi Ajagajigi-oogun ati Sisi Quadri ti won wole sun ni 2024

Gbogbo awa Omo Alade, a ma ku ilede. A ku ilede ti osere pataki, Alhaji Abdulsalam Sanyaolu, eni ti opo eniyan mo si Charles Olumo Agbako, to jade laye lojo die seyin.

Loooto, sabarumo je die lobi ki eyin to pon. Agbako ko ku ni rewerewe. O dagba, o fewu pari. Koda, o ferigi jobi ki o to je ipe Olodumare. Sibesibe, a gbodo maa ki ara wa ni ara f’era ku ni. Ki Odumare o fori jin in.

Eni ogorun odun o le’kan ni baba naa ko to t’eri gba’so. Ohun idunnu lo je pe bo ti d’agba to, ko rare laye. Koda, a gbodo kan saara si omo re, Iyaafin Motunrayo, to joko ti i ni ile re ni Sango-Ota. O duro ti baba re debi pe ise tiata ti oun naa n se, o fi sile die na. Ki Olorun je ki omo rere o toju oun naa.

Sisi Quadri

Bakan naa, awon osere Yoruba naa kare fun Agbako. Won se iranlowo ati ayesi fun un lojo ogbo. Bi a ko ba gbage lasiko ojo ibi re, nigba to pe eni ogorun odun, won sugba a re, ti won ba a jo, ti won si ba a yo.

Bakan naa, won tun pe e si oko ere lokesan laipe yii.

Ni pataki julo, osere fiimu Kunle Afod, se abewo pataki si Agbako. O si se bi o se maa n se fun awon agba osere, nipa nina owo owo si i. Lede kan de, o jo pe pelu idunnu ni Agbako ba jade laye.

Bi a se wa n se ‘o digba’ fun akoni osere naa, a ko le se alairanti awon onitiata Yoruba ti win fi aye sile ni odun yii. Ka ma paro, ka ma seke, ile n jeeyan.

Olofa Ina

Lara won ni baba olowe meriiri ti a mo si Olofa Ina. Bakan naa ni Ogunjinmi Ajagajigi Oogun to je pe ofo lo maa n tu jade lenu re pupu bi ejo. Odun yii naa ni iku mu omode jojolo, omo ikyin won lenje lenje lo, iyen Sisi Quadri, ti enu re mu bi abe fele, to fi maa n derin p’eeke awon eniyan pelu eebu abudigbolugi to maa n bu ninu fiimu.

Adura ni a o maa gba pe ki Olorun te gbogbo won si afefe rere. Ko Alawura ba wa mu iku aitojo ku. Ki Oba Nla fi iku rere pa gbogbo wa nigba ti a bagbo, ti a to.

Charles Olumo Agbako, o digba o.

Share this Article