O fi Naijiria sile sinu iwa ibaje
Tinubu ati opo eniyan kan saara si i lori ipa pataki to ko
Awon kan ti inu n bi n so odi oro si oku orun
Ipa wo ni ipeyinda re yoo ni lori idibo 2027?
Ogunna gbongbo ninu awon olori orile-ede Naijiria, Ogagun-feyinti Muhammadu Buhari, wo kaa ile lo lojo Isegun, ojo keedogun osu keje odun yii.
Ojo Aje Monday ojo kerinla lo teri gbaso ni ile iwosan kan ni ilu London, to si je eni odun mejile loggorin, iyen 82 years.
Opo eniyan, to fi mo Aare Bola Tinubu, ati awon akegbe re ni ile okeere, ni won ti n sedaro akoni to lo naa.
Ese ko gbero ni Daura, ni ipinle Katsina, to je ilu Buhari ti won sin in si.
Bee ni ogunlogo awon eniyan n yombo Buhari lojukoroju ati lori ero ayelujara.
Lara awon ohun ti won fi n kan saara si i ni ooto inu ati ikorira iwa ibaje.
Won n ranti idagbasoke to ba Naijiria nigba to je aare eleekeji ni odun 2015 si 2023.
Bi apeere, araye ranti bi o se ko afara agbayanu Second Niger Bridge, bi ijoba re se popona Lagos-Ibadan Expressway ati ilosiwaju to ba irinna oju irin.
Sugbon sa, ohun to koju si eni kan, eyin lo ko si elomiran.
Awon omo Naijiria kan ko korin rere ki Buhari, paapaa awon odo langba kan lori ero ayelujara.
Lona kinni, inu n bi won pe osibitu ile okeere lo ti maa n gba itoju nigba to wa laye, to si je pe ibe naa lo ku si.
O je edun okan fun won pe Buhari ati awon olori orile-ede yii ko ri idi lati da irufe ile iwosan bee sile nibi naa.
Bakan naa, awon to n binu ni Naijria ti Buhari n fi sile ko see mu yangan, to ji je pe o ni anfaani fun odun mejo gbako lati sise fun ayipada rere.
Sugbon, eyi to wu ka wi, Buhari ti se iwon ti apa re ka; o ti papoda; o si ti lo ba Olorun re.
Eyi tumo si pe orin ‘Ohun e ri e wi. Ohun e ri e ro …’ ni awon ebi ati ololufe re yoo maa ko.
Ohun kan to tun wa n ko opo eniyan lominu ni pe igbogun ti iwa jegudujera to je Buhari logun ko jo pe o so eso rere.
Kaakiri orile-ede yii, iwa jegudujera si n ba ilu finra.
Bakan naa, wahala darudapo eto aabo ti opo gba pe Buhari yoo le segun, tori bo se je ologun tele, si tun wa digbi niwaju Tinubu.
Sugbon, awaye ma lọ ko si, gbogbo wa ni a jẹ gbese iku.
Ki i ṣe igba akọkọ ree ti Buhari yoo wa si ilu rẹ ṣugbọn lasiko yii, wọn gbe wọle lai si ẹmi lara.
Ni dede aago mẹfa ku isẹju marun un ni wọn gbe Aarẹ ana, ẹni ọdun mejilelọgọrin wọ kaa ilẹ niwaju awọn iyawo, ọmọ, mọlẹbi, ara ati ọrẹ, pe o di gba, o di gbose.
Aarẹ Buhari lo ọdun mẹsan an ati oṣu mẹjọ ninu isejọba, eyi to jẹ apapọ ọdun to fi dari orilẹede Naijiria, gẹgẹ bii ologun ati aarẹ ti a dibo yan, eyi to sọ di olori to pẹ ju ninu itan orilẹede Naijiria.
Ọpọ awọn eeyan lo peju sibi eto isinku, lara wọn ni a ti ri iyawo oloogbe, Aisha Buhari, Aarẹ orilẹede Naijiria, Aarẹ Bola Tinubu; igbekeji rẹ, Kashim Shettima; igbekeji Buhari fun ọdun mẹjọ, Yemi Osinbajo; igbakeji aarẹ nigba kan ri Atiku Abubakar; oniṣowo, Aliko Dangote; awọn gomina ati gomina tẹlẹ, minisita, lọbalọba, olori ẹṣin ati awon mii.
Saaju eto isinku ohun, Tinubu tẹwọgba oku aarẹ ana ni paapako ofurufu Katsina ni kete to de lati ilu London.
Papakọ ofurufu Umaru Mua Yar’adua ni Tinubu ti gba oku naa, ki wọn to morile ilu Daura, nibi ti eto isinku ti waye.
Ipeyinda Buhari ati 2027
Pelu bi tele, Ogagun-feyinti Muhammadu Buhari, ti se dagbere fun aye yii, awon onwoye ti bere sii ro ookan ati eeji po lati mo ipa ti aisinile re le ko lori idbo aare ni 2027.
Eyi se pataki ti a ba ranti pe kii se oloselu to see fowo ro seyin nigba aye re.
O je eni kan ti awon oloyinbo le pe ni ‘one man battalion’, tori o ni obitibiti olutele to je oludibo leyin, ti won si feran re tokantokan.
Ohun ti a mo ni pe iye awon to maa n dibo fun un to milionu mejila.
Idi niyii ti awon oloselu fi maa n sugbaa re, ti won si maa n du u lotun-un losi.
Sugbon bayii, iku ti b’ola je; iku tii fo’lr adun, tii f’ole oyin.
Ibeere to se koko bayii ni pe: awon wo ni omoleyin Buhari n baa lo ni 2027?
Se egbe All Progressives Congress ni?
Se Peoples Democratic Party ni abi asesedasile ajumose African Democratic Party?
IROYIN OWURO gbagbo pe pelu bi ko ti si igbakeji kan pataki fun ajo oselu Buhari, ojo iwaju ni yoo so ohun ti yoo sele.