– Obafemi Hamzat, Wasiu Ayinde, Alabi Pasuma ba Bakare Oki-Olalekan ati awon osise LASTMA se ajodun
Bi ajo to n mojuto eto irinna ni Ipinle Eko, iyen Lagos State Transport Management Authority (LASTMA), se n se ayeye odun keedogon ti won da a sile, Gomina Babajide Sanwo-Olu ti se iranti bi Aare Bola Tinubu se fi ogbon iwoye ojo iwaju, ti awon oloyinbo n pe ni foresight gbe ajo naa kale.
Sanwo-Olu se eyi lasiko to n ki ajo naa ku oriire odun keedogbon, to si so ipa pataki ti awon LASTMA n ko ni idagbasoke oro aje ati kalo-kabo omoniyan.
Ninu atejade kan ti Gomina fi sori ero ayelujara, o fi idunnu han pe LASTMA tun ti jeun soke lori ise re pelu ero imo ijinle, iyen technological infrastructure, ti ijoba re n pese fun won.

Sugbon sa o, Sanwo-Olu kilo pe eni kankan ko gbodo digbo lu osise LASTMA kankan ti won ba n sise won.
O ni eni ba dan an wo, yo o dan tan, ti yoo si je iyan re nisu.
Lati abule IROYIN OWURO, awa naa dara po mo Gomina, ti a si n ki LASTMA ku ayeye ojo ibi odun keedogbon o.