Músò, músò! Ọjọ́ọ̀bí ọgọ́ta ọdún wọlé bá Sanwo-Olu láàrin ọ̀pọ̀ àṣeyọrí ní Ìpínlẹ̀ Èkọ́

Phenomenal
Phenomenal
Gov Babajide Sanwo-Olu

… Tinubu gbósùbà fún pẹ̀lú ìpèníjà lórí 4th Mainland Bridge

Mudasir Alabi

Ojo pataki ni Alaaruba, ojo keedegbon, 2025 je ninu aye Gomina Ipinle Eko, Alagba Babajide Sanwo-Olu o.

Ojo yii lo di enu ogota odun, iyen 60 years.

Idi niyi to fi je pe opo  eniyan lo n ba a yo, ti won n ki I ku oriire.
Lara won ni Aare Orile-ede yii, Assiwaju Bola Tinubu, to ki Sanwo-Olu fun ise takuntakun to n se ni Eko.
Tinubu tun wa ro gomina naa ki o se awon ise nla-nla to wa niwaju re ni asepari, ti afara agbayanu eleekerin, iyen Fourth Mainland Bridge, je okan ninu won.

Bi a ba wo o daadaa, ajoyo ti Sanwo-Olu n se je bii meji, tani ko ju bee lo.

Leyin wipe o di eni ogota odun, ijoba eleekeji re naa sese da si meji ni.

Ni pataki, ojo ibi pataki naa ba a ni enu ise nla gege bii gomina Ipinle Eko.

Ohun to maa fun u ni iwuri, idunnu ati ope fun Olorun ni pe ise goina to n se naa, o n ri i se.

Aseyori re f’oju han lona gbgbo.

Yala ninu eto eko, ilera, ipese ohun amayederun ati idagbasoke oro okowo, Sanwo-Olu n gbe awon igbese to wuri.

Sugbon nigba ti won ba maa ko itan ijoba ni Ipinle ko, o jo pe oun ti won a fi maa ranti Sanwo-Olu ju ni idagbasoke to ba erona oko oju irin.

Ni akoko, o pari ise lori oko oju irin Blue Rail ti Fashola bere.

Lona keji ewe, o ti pari Red Rail to je pe ijoba re lo bere.

O tun ti wa n fi oba le e nipa bibere eto lori bi Green Rail yoo se waye.

Nipa bayii, oun ni gomina to ti sise julo lori eto irinna reluwe.

Irufe awon aseyori re naa ni teru-tomo yoo maa so bi won se n ki I ku ayeye ojo ibi.

TAGGED: ,
Share this Article
Leave a comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *