Mudasir Alabi
- Àwọn nnkan pàtàkì mẹ́wàá tí àgbà ìsòwò náà ti ṣe fún ọmọnìyàn
Bi a ba n soro awon to lowo ju ni Naijiria ati Aafirika, a ko ni ka meta ti a fi maa daruko Otunba Mike Adenuga, to je oludasile ile ise Globacom ati awon ile ise okowo miran. Sugbon tori owo ti Adenuga ni nikan ko ni awon eniyan se maa n ranti re. Tori ohun to n fi owo ati ola re se lawujo ni. Bee, ka ma paro, ka ma seke, Adenuga le ma maa pariwo ni, o n na owo re si ibi to to ati ibi to ye.
Idi niyii to fi je pe lasiko ojo ibi re, bo se je pe o je eni kan ti ko feran ariwo bii eye ega, awon eniyan kan ko le ma ko o jade bi omo ojo mejo. Won ko le ma logun awon ipa nla to n ko lawujo fun araye. Bi won se n ki i ni won yoo maa ki i, ti elomiran ti Adenuga ti fi owo ola ba lara lai pariwo yoo maa royin, ti a fee to ile la.
Baba olowo naa to fi Banana Island ni ilu Eko se ibugbe, nibi to ko awon ile ti won te rere bii odo Osa si, di eni odun mejilelaadorin (72 years) lojo Isegun, April 29, 2025. To ba je olowo miran ni , ikede ibanisajoyo a gba gbogbo iwe iroyin, redio ati telifisan pa ni. Se owo ti yoo fi se bee ni ko ni ni? Sugbon Adenuga kii fe ki awon eniyan maa se eyi. To ba je pe o fe e ni, gongo iba so. Opo eniyan to ti soore fun, ti won ti dide lati ara re ni won ba maa figa gbaga lori ipolowo ojo ibi naa.
Sibesibe, lati nnkan bii ose meji seyin ni oniruuru apileko ti n jade lori igbesi aye gidi ti Adenuga n gbe.
Odun gidi ni odun to koja yii je ninu igbesi aye Adenuga. Lona kinni, Olorun ba a doju ti awon ota alaheso, awon ti won gbe ofege iroyin jade pe lapalapa ti ku. Aseyinwa, aseyinbo, imoran awon ota ko se lori Adenuga. Sakamaje lasan ni won ta bi okoto. Ero won, pabo lo ja si. Eyi wa tumo si pe oro Adenuga tope o ju ope lo.
Lona miran ewe, oro (wealth) Adenuga gberu sii laarin odun kan seyin. Gege bi awon atopinpin olowo Forbes ti gbe e jade, owo bii eedegberin milionu dolla ($700m) lo kun owo Adenuga lasiko naa. Ti a ba se eyi si naira, ile a kun falafala ni. K ma deena penu, owo to le ni tirilionu kan naira lo kun owo Baba Ijebu ti kii se ahun yii.
Bi owo re se n bureke sii, ni awon ile ise re naa n gbooro sii. Itumo eyi ni pe ilosiwaju n ba oawon ogooro eniyan to n sise pelu re. Owo tubo n wo apo ijoba lati owo re nipa orisiirisii owo orinto n san. Bakan naa, lai figbe ta, Adenuga n na owo lori orisiirisii nnkan to n ran ilu, elegbejegbe ati awon eniyan kookan lowo.
Abalajo, nigba ti Aare Tinubu n ki olowo tabua ti won n pe ni The Bull yii ko oriire ti ojo ibi, Aare se alaye pe o je ogunna gbongbo laarin awon ti won n mu ilosiwaju ba Naijiria. O ni o je eni ti ko see fowo ro seyin nidii ise okowo, ti ihuwasi re kii sii se ti eni to n se ipalara won awujo.
Bi IROYIN OWURO se n ki Otunba Dokita Mike Adenuga ku oriire, o je ohun amuyangan fun wa lati yannana awon ona bii mewaa ti Adenuga se n ran omoniyan lowo:
– Dokita Mike Adenuga je okan lara eni to n gba aimoye eniyan sise lawon ile ise re bii Globacom, ConOil ati bee bee lo. Aimoye osise re ni awon naa ti laami laaka.
– Dokita Mike Adenuga n gbe oniruuru ise fun awon kongila. Nipa bayii, awon kan ti la, won ti lu lati ara Adenuga.
– Dokita Mike Adenuga maa n diidi bun awon eniyan lowo nla-nla lati fi ran ebi ati ise won lowo.
– Dokita Mike Adenuga n gbe owo sile fun awon elegbejegbe ati ajo lati se awon eto pataki pataki. Lara eyi ni awon ti ile ise re bii Globacom maa n se nipa ohun ti won oloyinbo n pe ni Corporate Social Responsibility.
– Dokita Mike Adenuga n seun pataki fun oro aje Naijiria ati awon ipinnle nipa owo ribiribi ti oun ati awon ile ise re n sa lowo ori.
– Dokita Mike Adenuga n gbe asa ati ise Naijira soke latari bi Globacom se maa n fi owo gbe nnkan abinibi bii odun Ojude Oba ati Ofala ga.
– Dokita Michael Adenuga je opo pataki kan to je ki idagbasoke ise fiimu ati orin rinle ni Naijiria nipa iranwo nla to n se fun awon osere nipase eto Globacom Ambassadors.
– Dokita Mike Adenuga n yi kadara awon eniyan pada si rere latara eto tete orire Festival of Joy ti Globacom maa n se, nibi ti awon eniyan ti n je ile, je moto ati awon ohun meremere miran.
– Dokita Mike Adenuga n seto idagbasoke ere idaraya, gege bi Globacom se maa n se agbateru awon idije kan.
– Lakootan, Dokita Mike Adenuga twa lara awon akoni to je ki ibowofun wa fun awa eniyan dudu. Oun lo je ki araye mo pe omo Naijeria naa le da ile ise telifoonu igbalode sile, ti yoo si seto naa ti yoo ye kooro. Adenuga lo fi ye wa pe opolo olokowo dudu ko kere si ti oyinbo egbe re.
Nje aseyisamodun o, Otunba Mike Adenuga. Ki Olorun maa so agbara di otun.