Bola Afolabi
Gbajugbaja olorin Fuji, Alhaji Kollington, so pe oun ni olori onifuji.
O ni olorin ‘Ade Ori Okin’, iyen Wasiu Ayinde, ko le gba ipo naa niwon igba ti oun ba si wa laye.
O so eyi nigba to n fesi si ẹsun ti Wasiu fi kan an pe ko kaaramasiki lasiko ti iya oun ku.
Ninu iforowanilenuwo kan, K1 sọ bi o ṣe atilẹyin fun Kollington nigba iku iya tirẹ, ti o fi ẹsun kan an pe ko se bee fun oun.
Sugbon nigba to n soro ninu iforowanilenuwo kan laipe yi lori Agbaletu, Kollington tako esun naa.
O ni ohun gbiyanju lati kan si Kwam1 lori foonu, ṣugbọn ko gbe ipe rẹ tabi ki o pe pada.
Kollington tun fi esun igberaga kan Wasiu.
O ni oye Olori Omo Oba to je n gun un.
O ni: “Nigba ti iya Wasiu Ayinde ku, mo pe e ni ooto. Ko gbe e, bee ni ko da ipe naa pada. Koda lojo odun tuntun ni mo pe, ko si gbe e. Mo ni, kini nnkan to n sele si omokunrin yii? Nitori naa, mo je ki o ri I. Ko le so fun mi pe o n sise lowo.
“Kí ni ọwọ́ rẹ̀ dí fun? Bo ba je pe nitori o de ade ‘Olori omoba’, ipo naa wa fun idile re ni Ijebu, ki i se ti emi. Ṣé ó fẹ́ di Ọlọ́run ni? Emi ni olori gbogbo awon olorin fuji. Ko le jẹ olori rara nigba ti mo wa laaye.”