2027:Àwọn gómínà PDP fẹ́ gbọ̀’nà ẹ̀bùrú yọ sí Atiku àti El-Rufai

Phenomenal
Phenomenal
Bala Mohammed, Atiku ati Makinde

– Won l’awon o dara po m’egbe kankan

Akeem Lasisi

Irinajo Alhaji Atiku Abubakar si idije fun ipo Aare lodun 2027 tun ti fe di oni-kurukuru bayii o.

Idi ni pe awon gomina egbe re to je Peoples Democratic Party (PDP) ti ni awon ko fara mo ki egbe naa dara po mo eni kan kan.

Bee, erongba Atiku ni ki won se ara won losusu owo pelu awon egbe alatako miran.

Lara awon egbe to ti n f’okan si lara ni egbe Social Democratic Party (SDP) ati Labour Party (LP)

Koda, o ti n se oniruuru ipade pelu awon adari won.

Bakan naa, o ti n sise papo pelu Gomina Ipinle Kaduna tele, Mallam Nasir el-Rufai, eni to n binu gidi si Aare Bola Tinubu ati egbe re tele, All Progressives Congress (APC).

El-Rufai ti binu kuro ni APC, ti opo eniyan si gbagbo pe bi won ko fi se minisita lo kan-an loju egbo.

Oun lo wa n lo soke, to n lo sodo lati je ki awon oloselu alatako gbara jo, ki won si doju ija ko Tinubu ni 2007.

Lati je ki iru agbarijo alatako naa sise, egbe PDP se pataki.

Idi ni pe oun legbe to wa nile to tobi julo laarin awon alatako, bi o tile je pe ede aiyede ti je e ni edo horo.

Bakan naa, egbe naa lo ni gomina to po julo laarin awon alatako.

Pelu nini gomina naa, ireti wa pe awon ni won yoo gbe owo kale ti oro ibo ba doju re tan.

Se, oro idibo Naijiria, owo lowo, eyin nile ni; ati pe dibo koo sebe ni ohun ti opo eniyan fokan si.

Sugbon lasiko ti awon gomina naa se ipade pataki kan ni Ibadan, Ipinle Oyo lojo Monday, won ni ‘la’! awon ko ni je ki PDP dara po mo egbe kankan.

Won ko fe ki egbe naa fo mo awon lori, tori oun ni ategun fun won de ipo.

Bakan naa, awon amoye oselu fura pe awon gomina naa le ma fe ki Atiku je oludije fun PDP mo.

O jo pe oro Atiku ti su won, ti won si ni kaadi miran ti won fi si apo.

Bi won ba wa ko jale lati dara po mo egbe tuntun ti won fe da sile, a je pe oke nla miran tun ti wa niwaju Atiku niyen.

Eleyii a je oun ti egbe APC a dunnu si.

O tun fe jo pe oogun Tinubu fe mu awon ota re niyen.

Oro oloselu kuku soro da si.

Idi tun ni pe eni kan ko mo okan awon gomina PDP naa denu: boya won fe sise fun Tinubu ni.

TAGGED: ,
Share this Article
Leave a comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *