Bola Afolabi
Opolopo awon ololufe gbajugbaja onifuji ti a mo si Sefiu Alao ni won n ba a yo sese bayii, latari bi okan lara awon omo re Dokita Nofisat Adekunle,se ni itesiwaju ni ilu Oyinbo.
Arabinrin naa, to jo baba re bii imumu, lo n gba oye kun oye, to si n fi imo re se duniyan loore.
Bi apeere, o ti gba imo ijinle doctorate lati Walden University ni orile ede Amerika.
Eyi to tun je kasiara ibe ni pe imo ijile alakaso keji (MASTERS) meta ototo ni Nofisat ni lati University of Minnesota, the University of Buffalo, ati Plymouth State University, ti gbogbo won wa ni Amerika
Ni pataki, a gbo pe oga agba kan ni awunilori obinrin yii je ni gbajugbaja ile-ise ilu oyinbo Halliburton.
Ki a wa maa wo ise Olorun, nigba ti Nofisat n fi imo iwe dabira ni Amerika, baba re, Sefiu Alao, eni ti a tun mo si Original Omo Oko, je akorin to fi Abeokuta se ibujokoo,gege bi bi Rasheed Ayinde Fuji Merenge se fi Ibadan se ile.
Koda, awon ko gbe kadara won lo si Ipinle Eko bi awon akegbe won bii Adewale Ayuba, Abass Akande Obesere ati Osupa Saidi se se.
Sugbon e ko wa raye baii? Bi Sefiu tile se je ‘omo oko to gbo kirakira’ to, omo bibi inu re lo wa di araba ni ilu oba.
Olorun ma kare o. Ki Edumare tubo maa mu agbega ba Omowe Nofisat.