Darasimi, eni to je iyawo alariya ti a mo si Ijoba Lande, ti so pe okunrin naa ko ni owo to to egberun lona eedegberun naira (N500,000) lasiko ti awon sese pade, ti won si pinnu lati fera.
Darasimi so eyi lati tako awon to so pe tori owo ti Lande ni ni oun se fe e.
Nigba to n se alaye lori asemase to waye laarin oun ati osere fiimu Baba Tee, Darasimi so pe iro nla ni pe oun ti Lande ni itikuti tabi oun fe e ni ifekufee tori owo.
Arabinrin naa tun wa so pe oro ti Lande so pe opolopo okunrin lo gori oun kii se otito.
Ni ti oun ati Baba Tee, o ni asise ni, ati pe eku to da eyi sile nii je eda.
Eni to n so nipa re gege bii onidakudaa naa ni ore re Mary Gold.
O ni oun lo ni ki awon maa se ere gele ‘Truth or Dare’, ti nnkan fi wonu nnka mo won lowo.
Darasimi kabamo ohun to se naa, to si ni ki awon omo Naijiria fori jin oun.