Bola Afolabi
Osere fiimu ti a mo si Babatunde Taiwo, ti inagije re n je Baba Tee, ti pa awuyewuye ati awawi ti o, nipa titoro aforijin lowo alariyaakegbe re ti a mo si Ijoba Lande.
O ni ere ibalopo ti oun se pelu Darasimi iyawo Lande je eyi ti ko dara ati pe oun ko je se bee mo.
Ninu fidio kan to gbe si ero ayelujara, Baba Tee ni ere ‘Truth or Dare’ lo ti oun sinu nnkan itiju naa.
O be awon oloufe re ati gbogbo aye pe oun ko ni fi iru aso bee se eegun mo.
Lati nnkan bii ose kan ni awuyewuye ti gbale lori oro naa.
Lande lo koko figbe ta pe iyawo oun ti fi agbere ba ajosepo awon je.
O ni bo se na ba alara wonu yara lo na ajero wo o.
Asiko naa lo daruko Baba Tee.
Bi o tile je pe Baba Tee koko jo lo sotun ati osi, o papa jewo pe oun ba Darasimi sere ife.
O se alaye bi osere fiimu obinrin kan, Mary Gold, se mu Darasimi lo si ile oun ni Omole ni Eko.
O ni Mary Gold ni eku to da eyi sile to n je eda tori oun lo ni ki awon maa se ere gele ‘Truth or Dare’ naa.