Àwọn alágbára Ìpínlẹ̀ Rivers gungi rékọjá ewé, Tinubu bá fa jókà ‘ìmájẹ́ńsì’ yọ

Phenomenal
Phenomenal
Governor Similayi Fubara

Lasun Alagbe 

Bi bata ba n ro lako-lako ju, o n bo lori yiya ni.

Bee, Yoruba ni bi a wi fun omo eni a gbo: ori okere koko lawo.

Ki awon owe yii maa je ti awon alajaagbila oloselu ni Ipinle Rivers, nibi ti Aare Bola Tinubu ti gbe ijoba pajawiri kale bayii.

Irole ojo Isegun, March 18, ni Tinubu fi ibinu gba Gomina Siminalayi Fubara ati awon asofin ipinle naa si egbe kan, to si kede ajagunfeyinti Vice Admiral Ibok-Ete Ekwe Ibas gege bii alamojuto ijooba.

O ni osu mefa gbako ni nnkan yoo fi wa bee naa, pelu ireti pe won yoo wa woroko fi s’ada lasiko naa.

Nigba to n ba awon omo orile ede yii soro, Tinubu seranti ipa ti oun ti ko lati je ki alaafia ati irepo joba ni Rivers.

O se’ranti bi oun se pe awon alajaagbila si ipade, ti oun si parowa fun won ki won pari laasigbo to wa nile.

O ni ohun aidunni ninu ni pe pabo lo ja si.

Bakan naa, o se alaye ipa ti awon adajo, paapaa awon ti ile ejo to ga julo Supreme Court, ti sa nigba ti won gbe idajo kale.

Tinubu ni dipo ti awon onijagidijagan naa yoo se jebure, pata-poro ni won un n ba kiri.

O wa fi kun un pe iroyin ti oun n gbo lati odo awon alaabo ilu ko dara, to si fi kun un pe awon alakatakiti ti bere sii so ina si paipu epo robi.

Pelu oun to sele yii, opolopo oju ni yoo si ran mo Ipinle Rivers.

Won a fe mo bi awon agbaagba ibe yoo se huwa; won a si fe wo kin ni awon odo fe se.

Ni pataki, awon to nifee alaafia yoo maa gbadura ki oye idi ti ipari ija se gbodo wa llaarin Gomina ti won gba segbee, iyen Siminalayi Fubara, ati oga re tele to je Minisita  fun Abuja, Nyesom Wike, o fi ye won.

TAGGED: ,
Share this Article
Leave a comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *