Akeem Lasisi
Ile ifowopamo First Bank ti tun fihan pe oun ni baba bayii o, pelu bo se bere kiko olu ileese kasiara miran ni ilu aramanda Eko Atlantic City ni Ipinle Eko.
Kii se pe First Bank ko ni olu ilesse to see fi yangan tele.
Eyi to wa ni Marina, gabankogbi ni.
Ara naa lo kan fe da.
Se bi a sa keke ogun, aajo ewa la fi se; bi a si fa abaja ogbon, jo ewa naa ni.
Koda ka fi oju sile ni gombo, aajo ewa naa ni.

Olu ileese eyi ti ile ifowopamo ti je akoko ni Naijiria sese bere sii ko yii, aragbayamuyamu ni.
Iyen ni oloto to ni t’oun oto.
Ile naa ni yoo ga julo ni orile-ede Naijiria.
Se lojoun, Cocoa House la ma si ile akoko to ga julo ni Naijiria.
Sugbon eyi ti First Bank n gbe bo yii, aja metalelogoji (43 storeys) lo ni.
Kii waa se giga fiofio nikan ni o, bi won se fee ko o, arakenge ni.
Awon ohun alumooni, imo ero ati ohun itesiwaju oro aje ti yoo wa nibe koja ohun ti a n royin.
Idi niyi ti opolopo awon eeyan ja-n-kan-ja-n-kan se sugbaa First Bank ni nnkan bii ose kan seyin, nigba ti won n kede ibere ise lori ile naa.
Koda, Aare Bola Tinubu naa ba won yo sese.
Igbakeji Aaare, Kashim Shettima; Gomina Ipinle Eko, Babajide Sanwo-Olu; Alaga First Bank, Femi Otedola ati ore re olowo tabua, Aliko Dangote, pelu opo awon eeyan nla-nla lo wa ni Eko Atlantic City lojo naa.
Nigba ti Shettima, eni to soju Aare Tinubu n soro, o fi idunnu han pe First Bank se bi akoni, leyin pe o n mu itesiwaju ba oro aje.
O ni igbese ti banki naa gbe je eyi ti yoo tun je ki igbagbo tubo wa ninu oro aje Naijiria.
Bakan naa, Sanwo-Olu dunnu sinsin, to si kan saara si First Bank.
Inu Gomina dun pe Eko Atlantic ti di gboregejige, ti First Bank naa si gbe igbese itesiwaju nipa kiko olu ileese nla naa sibe.
Idi niyii ti inu Sanwo-Olu fi dun nigba ti o gbe iwe eri ifunni nile fun awon alase banki naa ningbangba walia.
Otedola, eni ti opo eniyan gba pe o wa lara awon to se agbateru lilo First Bank si Eko Atlantic, kan saara si ijoba apapo, ijoba Ipine Eko ati awon alase Eko Atlantic.
O wa mu u da awon eniyan loju pe teru-tomo ni yoo maa je anfaani itesiwaju ti First Bank n se naa titi ayeraye.
Oga Agba fun banki naa, Olusegun Alebisou, naa n rerin-in idunnu bi gbogbo aye se yi i po, ti won si n pohun rere First Bank.
O se alaye hulehule awon ohun meremere ati ise ribiribi, eyi ti yoo tubo mu ilosiwaju ba banki naa, Ipinle Eko ati Naijiria lapao, eyi ti won yoo maa gbe se ninu ile kasiara naa.
Lai deena penu, IROYIN OWURO ki First Bank ku oriire.
Olorun a pari ile nla naa layo.
Bee, ilosiwaju nla-nla ni yoo maa ba ile Yoruba, Ipinle Eko, Naijiria ati Aaafirika lapapo o.