TAMPAN fi òfin de àwọn ọmọ ẹ́gbẹ́ lórí gbígbé èdè àìyedè lọ sórí ẹ̀rọ ayélujára

Phenomenal
Phenomenal
TAMPAN President, Bolaji Amusan, aka Baba Latin

Egbe awon elere tiata ati fiimu, iyen Theatre Arts and Motion Pictures Practitioners Association of Nigeria (TAMPAN), ti fi ofin de ki awon omo egbe maa sare gbe oro ede aiyede lo sori ero ayelujara o, ti a mo si social media.

Aare egbe naa, Alagba Bolaji Amusan, ti a mo si Baba Latin, lo se ikede ipinnu yii lasiko ti won n se ajodun ati ipade olodoodun won ni ilu Eko.

O ni o ti di dandan bayii ki omo egbe koko fi awuyewuye to awon olori egbe leti, ki won le ba won yanju ohun to ba n sele ni itunbi inubi.

Gege bi Latin se so, awuyewuye ori social media n fa rukerudo, to si maa n ba nnkan je.

O wa ro awon omo egbe ki won maa gbe aye irepo, ki won si maa ranti pe aheso kii mu ilosiwaju ati alaafia wa.

Lara awon osere fiimu ti won pejo sibi ipade naa to waye ni Tayo Aderinokun Hall, ni ifafiti ti Eko, iyen University of Lagos, ni Dele Odule, Adebayo Salami, Jide Kosoko  ati Bose Aregbesola.

Lasiko ipade naa, won fi oruko idije ere ori itage ti won maa n se lodoodun se eye fun Alagba Odule, to ti wa di Dele Odule Theatre Competition.

Gege bi Latin se so, eyi waye lati fi idunnu egbe TAMPAN han si gudugudu meje ati yaaya mefa ti Odule ti se fun itesiwaju asa, ise, ere fiimu ati TAMPAN gan-an.

Odule naa dunnu sinsin, to si dupe lowo gbogbo omo egbe.

Ibe naa lo ti kede pe, lodoodun, oun yoo maa fun TAMPAN ni milionu kan naira, fun eni to ba gbegba oroke ninu idije naa.

Share this Article
Leave a comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *