Omotola gbá kámú lórí àpá tí isẹ́ abẹ dá sí i lára

Phenomenal
Phenomenal
Omotola

 Bola Afolabi

Yoruba bo, won ni kii ba ni ka yeri.

Bee, iku to loun a pa ni, to ba si ni fila ka dupe lo to.

Gege bee ni oro gbajugbaja osere Noliwuudu, Omotola Jalade-Ekeinde, je bayii.

Ailera nla kan se e lodun to koja lo, to si je pe Olorun lo la emi re.

Lasiko isele naa, awon dokita sise abe fun un, eyi wa fa apa si ikun re.

Gege bii gbajugbaja orekelewa, ko ni fe ki abaawon kan ta ba ara tabi awo oun.

Sugbon, kii ba ni ka yeri.

Oro apa naa maa n ko o lominu tele, sugbon o ti fi oro ara re se iwaasu bayii pe oun ki gba a ni ara kadara oun.

O ni inu oun ko rupo mo bi oun ba ru apa naa tori nile aye yii, ki eniyan maa dupe lowo Olorun, ko si maa dunnu lori gbogbooun to ba de ba a ni.

Ninu apileso kan lori ero aye lujara, Omotola wa ro gbogbo eniyan pe ki won ma fi ironu se ara won lese lori nnkan kan.

TAGGED:
Share this Article