Gbajugbaja oniroyin ati asoro lori ayelujara, iyen Kemi Olunloyo, ti bu enu ate lu bi Priscilla, to je omo elere fiimu Iyabo Ojo, se tun n wo aso to n fi oyan sile labalaba o.
O ni eyi ko tona mo leyin to ti di abileko.
Bi a ko ba gbagbe, Priscilla se igbeyawo pelu ololufe re to je omo orile-ede Tanzania lojo die seyin.
Lori Facebook, Olulnoyo se afihan foto kan ti omodebinrin naa tun sese gbe jade, nibi ti pupo ninu obitibiti aya re ti wa ni ita.
Olunloyo ran an leti pe idile Musulumi lo ti loko, ko ma wa fi ayo ba idunnu re je.