YORUBA KU ASEINDE: Iku to pa Awolowo, to pa Abiola, to pa Ayinde Barrister tun wole o mu ogunna gbongbo oniwaasi Aafaa Muyiden Ajani Bello lo
Fẹ́mi Akínṣọlá
Otito ni pe kii se iroyin gbigbona felifeli mo pe ogbontarigi oniwaasi Musulumi, Sheikh Alhaji Muyideen Àjàní Bello, ti síwọ́ iṣẹ́, ti wọ́n sì ti sin-ín nílànà ẹ̀sìn nla naa lọ́jọ́ Jímọ́ọ̀, ojo kefa, osu kejila odun 2024. Bee, àdúrà ọjọ́ kẹta ti wáyé ní gbàgede pápá à ṣeré Adámásingbà nílùú Ìbàdàn lọ́jọ Àìkú níbi tí ojú àwọn èèkàn ìlú ti pé tí wọ́n sì tọ́rọ, bèèrè àánú Ọlọ́run Allah fún
Àgbà oníwàásí yìí. Sibe sibe, ogooro eniyan kaakiri agbaye, paapaa awon omo Yoruba, ni isele iku ojise nla naa si n se ni kayefi.
Idi ni pe, ipo ti Aaafaa Muyideen wa ninu esin ni a le fi we ipo ti ieu Oloogbe Obafemi Awolowo wa ninu oselu, ati eyi ti Oloogbe MKO Abiola wa ninu ise okowo ati oselu bakan naa.
Ti a ba tun wo aarin awon osere tabi elere alariya, iku to pa Sheikh Muyideen a tun ra wa leti bi iku Hubert Ogunde, Sikiru Ayinde Barrister ati Gbenga Adeboye se gbe koto ti ko se di si awujo wa. Akanda eda ni won ni ilana ti okookan won di mu. Bee gege ni Alhaji Ajani Bello se je laarin oniwaasi Musulumi. Tenu ko, tete booli ko, iru lebe ko tun si ninu eegun mo.
Idi niyi ti Ìròyìn Òwúrọ̀ se fe se ise atotonu pataki lori àwọn àmúyẹ ìwà tí Àgbà oníwàásí yìí gbé dúníyàn hù àti àyípadà rere tó mú bá ìgbé ayé ọmọnìyàn, ìdílé, Nàìjíríà àti àgbááayé. Ìdí pàtàkì nìyí tí á fi fẹ́ ẹ́ túṣu désàlẹ̀ ìkòkò nípa àwọn ìrìnàjò ìgbésí ayé bàbá yìí, kó má a jẹ́ àwòkọ́ṣe fún ìran yìí àti ìran tó n bọ̀.