GÓMÌNÀ ÈKÓ LẸ́YÌN SANWÓ-OLÚ: Tá ni Ifá máa mú ní 2027?

Phenomenal
Phenomenal
Sanwo-Olu

Lasun Alagbe

Bi a ba fe fi oju sanponna wo o, ona 2027 si jin gan-an. Odun naa ni Alagba Babajide Sanwo-Olu yoo pari isejoba eleekeji re. Sugbon ti a ba fe fi oju oloselu wo o, ojo naa ko jinna mo rara.

Idi ni pe awon oloselu ti bere sii wo fetofeto, ti won n da ofun tolo latari bi won se le de ipo naa.

Bi apeere, laarin ose kan seyin nikan, iroyin  meji jade lori idibo 2027 ni Ipinle Eko, leyii ti o ran mo oruko awon oloselu pataki meji kan.

Hamzat

Eni kinni ni Abenugan Ile Igbimo Asofin ipinle naa, Onarebu Agba Mudasiru Obasa; nigba ti omo bibi inu Aaare Bola Tinubu, Arakunrin Seyi Tinubu, si je eni keji.

Ni ona kinni, Obasa so gbangba pe oun ni buruji ati gbogbo awomo lati di gomina Ipinle Eko. O ni ko si ohun ti aja se ti obo ko se. O ni gbogbo awon to ti di gomina ko ni ohun ti oun ko ni. Sugbon sa o, Obasa ni kii se pe oun ti n kede pe oun setan lati du ipo gomina naa, sugbon o ye ki araye mo pe on kii se eni ti eni kan le fowo ro seyin.

Ambode

Ojo ti Gomina Babajide Sanwo-Olu lo si Ile Igbimo Asofin naa, nibi to ti gbe Idabaa Eto Isuna odun to n bo, eyi to je tirionu meta naira, kale, ni Obasa ti so ti enu re jade.

Ni ti Seyi Tinubu, awon ajo odo langba kan ni won ni awon ti fi ounte lu u pe ki o gbe apoti gomina Eko ni 2027.

Won soro labe asia ajo the Coalition of Nigerian Youth Leaders (CONYL).

Won ni Seyi Tinubu je oniwa to see f’okan tan, ti kii sii da epo moyo.

Insecurity: Lagos Assembly to transmit protesters’ petition to FG, NASS
Obasa

Bi o tile je pe awon eniyan kan ti  soro lati tako awon CONYL, ohun to se pataki ni pe won ti fi ohun sile. Bee, Seyi gna-an funra re ko tii so pe oun ko le se ohun ti won so.

Awon to ba n fi okan ba oro ta ni yoo di gomina leyin Sanwo-Olu lo yoo ranti pe aipe yii naa ni oro Gomina ana, Alagba Akinwunmi Ambode, naa jeyo.

Eyi waye leyin ti o se ipade kan pelu Gomina Sanwo-Olu, ni ile ijoba, ti Sanwo-Olu si so oro bi owe, bi owe, pe oro ojo iwaju Ipinle Eko ni awon se ijiroro le lori.

Eyi je ki awon eniyan kan maa ro pe o seese ki Aare Bola Tinubu ti dari jin Ambode, ki won si wo o pe ki oun naa wa se eekeji.

Hmmm. Oro oloselu, nnkan nla!

Sibesibe, awon amoye ranti pe eni to je igbakeji Sanwo-Olu, iyen Dokita Obafemi Hamzat, naa n be nile, ti oun naa si ni’fee si ki oun de ipo leyin oga re.

Bi a ko ba gbagbe, Sanwo-Olu ati Obafemi ni won jo figa-gbaga ninu idibo abele APC ni odun 2019, ki kinni naa to ja mo Sanwo-Olu lowo.

 

Pelu alaye ti a se s’oke yii, o daju pe awon mereerin ti oruko won jeyo lo ni ikimi.

Se Seyi, omo olori oko bambam la fe so ni? Omo Ifa to maa n mu oba! Ohun ti opo eniyan kan maa ro ni pe Tinubu  le ma fe huwa bii alajetan nipa pe ki oun je Aare, ki omo oun tun je gomina Eko, Ipinle to je pe o ju opo orile ede miran lo nipa titobi oro aje.

Bakan naa, Ambode je eni kan ti o ti se e ri. Awon eniyan ti ri  aseyori re, ti oun naa si ti ri asise ara re. Nitori idi eyi, kii se eni ti o see fowo ro seyin. Ibeere to le jeyo lori tie ni pe, se awon to dide ogun ni 2019 ti jebure?

Obasa naa kii se kekere oselu. O ti se alaga ni Agege ko to di Abenugan ni Ile Igbimo Asofin. Nitori idi eyi, odu ni ti kii se aimo oloko. Sugbon sa o, se awon kan ko ni maa beere pe se oun nikan ni won daye fun ni?

Ni ti Hamzat, o ti huwa bi oloselu to fara bale daadaa. Ko gbo oga re Sanwo-Olu lenu, to si fowo sowo po lati maa se ise ribiribi ti won n se. Ibeere to le waye lori tie ni pe nje eni to ti se igbakeji ni Ifa maa mu?

Lapapo, opo eniyan yoo nii lokan pe Olorun lo mo okan Aare Tinubu funra re. Bayii, a ko tii mo awon miran ti won maa jade nigba to ba to asiko.

Tinubu

Bakan naa, gbogbo ohun to wu ki awon eniyan maa ro, gbogbo ohun ti Tinubu funra ara re le ni lokan, o daju pe eni to ba maa fi ounte lu, to ba maa se ipalara fun ibo eleekeji re ni 2027, ko ni gboorun tikeeti naa.

Idi ni pe a kii so ori olori ki awodi o gbe teni.

Share this Article