Akeem Lasisi
Ile ise Globacom tun ti fihan pe o-wi-bee-se-bee ni oun o lori ajodun oloriire Festival of Joy to maa n se lodoodun, nibi to ti maa n fun awon eniyan ni orisiirisii gbankogbi ebun.
Ni bayii, o ti bere sii pin moto, owo nla ati awon ebun miran fun awon oloriire omo Naijiria.
Bi apeere, ni ilu Wrri, Ipinle Delta State, okunrin oloriire Daniel Mayuku, ni Globacom ti gbe moto jiipu tuntun tear-rubber fun, nibi ayeye kan ti won se ni bi ojo meta seyin.
Inu Mayuku dun de eyin, to si n kori n rere ki Globacom.
O ni nigba ti won ko pe oun pe oun je ebun kabiti naa, oun ko se bi eni pe oun gbo, tori o ro pe awon okuro 419 ni.
Sugbon nigbeyin-gbeyin, o ri i pe Globacom ko fi oro naa se wasa rara.
O wa dupe lowo ile ise naa ti gbajugbaja onise okowo Otunba Mike Adenuga da sile.
Mayuku nikan ko ni Globacom ti gbe ebun nla fun ninu Glo Festival of Joy 2024 o.
Bi apeere, awon kan ti je ebun milionu naira kookan, ti Globacom si ti fun won ni sowedowo lai fota pe.
Lara won ni Arakunrin Olieh Somtochukwu, to n sise ni Ipinle Anambra; Iyaafin Adebayo Idowu, eni to sese feyinti ninu ise olukoni; ati Arakunrin Sanni Ganiu Bayo, to je atewe (printer) to fi ilu Eko se ibujokoo.
Awon ti Globacom tun ti so di milonia ni Abdul Mumuni Oseni (direba ile ise kan), Abiodun Oluwasanmi Temitayo, (onimo ero) ati Ashimiu Aminat Idowu, to je olukoni.
Nigba to n soro lori ipolongo naa, oga agba kan ni ile ise Globacom, Ogbeni Mojeed Aluko, ni ko nira rara lati kopa ninu idije naa.
O ni awon ibeere gbefe lasan ni olukopa yoo dahun, tabi ki won kan yi taya oloriire.
Lati je lara awon ebun pataki yii, awon to wa lori ikanni Globacom ni lati pe *20152# or, tabi ki won fi JWD ranse si 20152 lori opo Glo line won.