Èyí o wù á wí: Ìjà Taye Currency àti Pasuma fihàn pé orin fújì sì lérò lẹ́yìn pitimu

Phenomenal
Phenomenal
Currency

 Lasun Alagbe

Nigba ti orin hip hop koko bureke ni Naijiria, eru ba awon awoye kan  pe afaimo ni ki o ma pa irawo orin fuji re. Asiko yii ni awon D’Banj , Olamide ati bee bee lo sese n da bii edun ti won n ro bi owe.

Ka ma paro, ka ma s’eke, awon onifuji kan naa se ojo die nigba naa.

Bi apeere, awon bii Wasiu Alabi Pasuma ati Saheed Osupa, to je pe awon akorin oyinbo maa n sa lo ba pe ki won ba won se ikorinpo kolabo tele, naa wa di eni to n pe awon eru iku hip hop ki won wa kobalo pelu awon. Sugbon sa o, leyin odun die, awon onifuji naa tun fi ogbon ati oye te orin won nidii, won tun sise karakara, ti won si tun pada si aaye won lori itage orin.

Lona kinni, fuji  ko ku bee ni ko run. Lona keji ewe, o tun taari ara re si ipo giga, ti oun naa di gbajugbaja lori ero ayelojara intaneeti ati social media.

Pasuma

Bi eni kan ba wa ro pe fuji ko si lori gongo okan opo eniyan — to fi mo awon alakowe — gbonmi-si i-omi-o-to-o to n waye laarin Pasuma ati ajumorin re, Taye Currency, ti je ko ye won yeke bayii pe  oke si ni fuji wa tente. Iso ti Currency ati Paso n so, oorun re n run gbai kaakiri agbaye ni.

Lenu nnkan bii ose die seyin, oro awon mejeeji, ati awon ti oro ija naa tun n ta ba, bii Wasiu Ayinde Barrister, Osupa, Titi Leather— ni won di oun ti opo eniyan n so nipa won.

IROYIN OWURO ko so pe ohun to dara ni pe ki awon osere mejeeji maa ja, tabi ki ruke-rudo maa lo ni awujo olorin. Sugbon, bi a ba n sunkun, a maa n riran. Bi oore se wa ninu igi naa ni ibi wa ninu ire. Ki Olorun je ki alaafia o joba lagboole fuji. Ati ni ile Yoruba toun Naijiria pata.

Share this Article