Èmi gan-an gbéégún rí. N kò jẹ́ bá wọn tàbùkù ìsẹ̀ṣé – Yinka Ayefele

Phenomenal
Phenomenal
Ayefele
 Biola Afolabi

Akorin emi pataki, Yinka Ayefele, ti fesi le esun kan ti awon kan fi kan an pe o n ba awon onisese loruko je.

O ni laye, oun ko je bu onisese tabi ki oun te won loju mole tori omo odo agba ni oun naa, bo tile je pe elesin Kririsiteeni ni oun.

Ayefele, eni to tun je oludasile ile ise redio ‘Fresh FM’, koju ipenija latari arakunrin kan to se iforowalenuwo fun, ti o si so bi oun se pa opo eniyan, ti oun tun maa n je eran ara won.

Okunrin naa ni oun ti gba Jesu bayii, sugbon o ti dan mewaa wo nigba kan.

Ninu oro re naa lo ti so pe awon onisegun kan lo maa n ro un lagbara, nigba ti emi apomolekun-jaye naa gbe oun wo.

Idi niyi ti awon kan fi so pe okunrin karanbaani naa ati Ayefele n ba isese loruko je.

Sugbon nigba to n so ti enu re ninu fidio kan ti gbajumo arosro lori eyelujara Yinka TNT n ba a f’oro jomitoro oro, Ayefele ni okunrin naa kan so nipa igbesi aye re ni.

O ni oun ko so pe awon onisese lo ni ko maa paniyan, ti oun ko si n koyan isese kere rara.

Ayefele ni nigba ti oun si wa ni ilu awon in Ipoti-Ekiti, oun maa n gbeegun, ati pe lori eto oun lori redio, oun ko le ma juba awon agbagba naa.

TAGGED:
Share this Article