Egbìnrìn ọ̀tẹ̀ lágbolé fújì: Àbúrò Ayinde Barrister, Gani Balogun, ní ẹ̀san ló ń ké

Phenomenal
Phenomenal
Ayinde Barrister

Bola Afolabi

… Wasiu Ayinde gbe igbese alaafia

Roforofo to n sele lagboole fuji bayii da bii egbionrin ote: bi a se n pana ikan, ni ikan n ru.

Lasiko ti  akorin gbajugbaja to wa laarin rotiroti naa, iyen Wasiu Ayinde K1 de Ultimate, n parowa ki onikaluku o jebure, aburo Oloogbe Sikiru Ayinde Barrister, Alagba Gani Balogun, ti se atupale nla kan lori itan fuji.

Itan idasile fuji, ati ipa ti Barrister ko, ti awon kan n gba si otun ati osi, lo da awuyewuye to n lo sile.

Bi apeere, Saheed Osupa n ba Wasiu fa surutu lori pe o so pe ti oun ni fuji, ti Osupa si gba pe, lojokojo, Barrister ni ori fuji.

Kollington Ayinla

Ija eyi n waye leyin ti Taye Currency koko fi orun wu yanponyanrin sile lori ibasepo to wa laarin oun ati Alabi Pasuma.

Ni pataki, aburo Ayinde Barriste naa, iyen Gani Balogun, gbe apileko kan jade lori ero ayelujara ni ojo Satide, nibi to ti so pe esan lo n ke lori awon agba fuji bii Wasiu Ayinde ati Kollignton Ayinla, latari bi awon onifuji ti won juwon lo se n gbo won lenu.

Lona kinni, Balogun se alaye pe ko si awo orin kankan to fihan pe fuji ti wa ki Ayinde Barrista to fi ipile fuji ti teru-tomo n je di oni lele. O ni eni to ba ni eri pe eni kan gbe awo orin fuji jade ki Barrister to se bee ni 1974, ko fi han araye.

Wasiu Ayinde

Bakan naa, Balogun ni ti Kollignton ba gba pe Barrister lo wa ni ipo kinni nigba to wa laye ni, ko si eni ti o maa  ba oun naa du ipo naa bayii.

O tun fi kun un pe koda nigba ti Barrister to je oga Wasiu Ayinde wa laye, Wasiu maa n fi orin gun un garagara nigba iran.

Gani Balogun

Arojinle ti Balogun wa ni pe bayii ti awon to tele Kollignton ati Wasiu naa wa n yan fanda, ti onikaluku si n so pe oun loga, esan, eyi to pe ni ‘kharma’, lo n ke.

Share this Article