Ẹ FURA O! Ọ̀nà méje ọ̀tọ̀tọ̀ tí àwọn tó ń ta epo bẹtiró fi ń gbá onímọtò

Phenomenal
Phenomenal
NNPC
Oga agba NNPCL , Mele-Kyari

Bola Afolabi

Bi o ba wo ile epo kan lati ra betiro tabi disu, ti oluta, iyen petrol attendant, ba fi erin pade re, to si n ki o ni mesan-an mewaa, yara fura o. Kii se pe o nifee re denu. Kii se pe inu re dun dele si o. O fe gba o ni o!.

O kan fe de ori re mo agolo pelu oyaya eke ni. Lopo igba, eyi je ona kan ti awon oluta epo fi maa n ja onibara won lole. Nigba ti won ba ti da oyaya bole, o ko ni le fura pe won fe se ise ibi. Koda, o le ma wule wo oju gilaasi onka nibi ti mita ati owo ti n sare tete mo.

Eyi to tun fi ara pe eyi ni ki oluta naa da oro kan sile nigba to ba n ta epo lowo. A fe ki e jo maa woju ara yin, dipo ki o maa wo oke nibi owo ti n sare tete bi eku agege ni. Bee, oun mo jibiti ti o fe lu. Lasiko ti lita epo kan ti n le ni egberun kan naira (N1,000) yii, awon modaru elepo naa mo pe bo ba je lita kan pere ni awon ri ji mo o lara, owo gidi ni. To ba le se bee fun eniyan mewaa lojumo, oun naa bo saye niye. Ka yara fura o!

Ona miran ti won fi maa n gba onibara won ni nipa ki won maa te irin ti won fi n po epo – iyen nosu – ni ite modaru. Lona kinni, o le te nosu naa ni aabo, ko ma te e kanle. Eyi le fa ki epo ma da gooro to bo se ye ko da sinu tanki tabi keegi. Lona keji ewe, o le maa fi owo jaaki nosu naa, ti meta yoo maa ka, ti epo ko si ni bo sinu tanki bo se fe. Se e ri awon modaru elepo ti a n wi, Olorun lo mo nomba ile won o.

Bakan naa, awon laabi tepotepo to ye ka maa pe ni jepojepo naa le so fun o pe ki o maa wo mita o. Won a maa so lemolemo pe ki o teju mo mita. Won ko fe ki o wo owo awon ni o. Sugbon bi iwo se n wo mita ni ki o maa wo owo buruku naa. Tori owokowo, owo ejo sebe oloro lo fe lo.  Ohun ti eyi tumo si ni pe epo le pe lori gilaasi onka, ko ma pe rara ninu tanki.

Ko tan sibe o, awon oluta miran le se bii pe awon ko gbo iye epo ti o ni ki won ta. Bi apeere, o ni ki won ta epo egberun lona ogun, iyen N20,000. To ba ti wa ta epo bii egberun mewaa, o le da nosu duro. Ti iwo ko ba woke daadaa, o le so pe o ti pe, ko sare pa mita re. Bi o ba si ri ete re naa, ibi to ba ti fe ta eyi to ku fun o, modaru kan maa n saaba sele. Nipa bee, o le padanu epo bii egberun meta naira si marun-un. E o wa ri i pe aye le bi.

Leyin eleyii, awon omo jaguda elepo miran maa maa n yo ju iye to ye ki won yo lori kaadi ATM. Ibi to ba ti ye ko te N10,000, o le te 20, tabi ko f’oba le e, ko kuku te N100,000. Itumo eyi ni pe o ye ki eniyan maa ye risiiti re wo daadaa ko to kuro ni ile epo.

Gbogbo eyi ti a ti n ro lejo lati eekan, awon oluta petrol attendant la n ba wi. Awon onile epo gan-an nko? Awon kan naa maa n se modaru laarin won. Won maa n yi mita ni ayipa, Idi nyi ti epo oni N10,000 ni ile epo kan le kere tabi ko po ju ti ibomiran lo. Lati mo eyi, ko si ohun to buru ninu ki eniyan fi keegi se idanwo fun awon ile epo ti eniyan ba ti n ra epo. Ogbon lo gba. Ati pe bi omo ba j’agbon kuku, iya re naa a jagbon sinsin. Koda, bi omo ba jagbon kuku ni eerun, iya re naa jagbon sinsin si pado.

Ka fura o!

TAGGED:
Share this Article