Ó ní: ‘N kò mọ̀ pé le dé ipò ti mo wà lónìí yìí’
O se eto pataki fun awon omi ile iwe l’Agege pelu ebun owo
Opo eniyan ki i ni aseyis’amodun
Akeem Lasisi
Yoruba ni bi eru ba mo inu ro, yoo mo ope du. Owe yii je ti Abenugan Ile Igbimo Asofin ni Ipinle Eko — Lagos State House of Representatives — Rt. Hon. Mudashiru Obasa, eni ti o pe aadota odun le meji laye ni ojo Monday, ojo kokanla, osu kokanla, odun 2024.
Odun 1972 ni won bi Obasa ni ilu Agege, ilu ti kii fi i sere rara.
Bi a ko ba gbagbe, Obasa ti je Alaga Ijoba Ibile Agege ni 1999 si 2002, ko to jeun soke, to bo si ile igbimo asofin.
Niwon igba to je pe ori nikan lo mo ibi to n ba ese re, Obasa gan-an ko mo pe kadara pese ibi to tun ga fiofio siwaju de ohun.
Funra re lo so eyi ni ojo Jimoo to lo, nigba to se eto pataki kan fun awon omo ile-iwe kaakiri awon sukuu kan ni Agege.
Opolopo eeyan nla-nla, to fi mo awon asofin Ipinle Eko, ni won rogba yi Obasa ka nibi eto naa to waye ni Oyewole Primary School.
Nigba to n so oro iyanju fun awon omo ile iwe naa, o ranti bi oun naa se je akekoo bii tiwon nigba to wa ni omode.
O gba won ni iyanju pe ki won gbaju mo eko won.
O ni ti won ko ba fi eko sere, ti won foju si ohun ti oluko n ko won, ti won ko si da oro obi won nu, ojo iawju won yoo dara pupo.
Obasa ni, “Igba ti mo wa ni omode bii tiyin, n ko mo rara pe mo le de ipo ti mo wa lonii. E jowo, e sara giri, e fi tookan-tara si eko yin, e o si wa ri i pe oriire to duro de yin niwaju ko lopin.”
Nibi eto naa, Obasa ati awon asofin yoku fun omo ile-iwe kan ti oruko re n je Alege Oluwadarasimi Aminatu ni ni ebun eko ofe ti iye re je milionu marun-un naira — N5m.
Aminatu ni ibon olopaa kan ba ni aipe yii.
Bakan naa, awon omo ile-iwe meji ti won se daadaa ju ninu idije current affairs ti won se lara eto ojo ibi naa gba ebun owo, nigba ti won si fun Oyewole Primary School, Thomas Aquinas School ati Royal Apple School ni komputa meedogun.
IROYIN OWURO ni ife si Obasa tori o ni ife si igbega asa ati ede Yoruba. Olorun tun wa kee nipa pe Gomina Ipinle Eko naa, Alagba Babajide Sanwo-Olu, ko koyan asa, ede, ati ise alariya kere rara.
A woye wi pe, laarin awon Abenugan kaakiri ile Yoruba, Obasa lo jo pe ede Yoruba je logun ju.
Eyi ni ko fi yani lenu pe, labe asia re, Ile Igbimo Asofin Eko seto ki won maa lo ede Yoruba naa nigba ti won ba n se apero.
Pelu eyi, Obasa fihan pe ko si ohun ti onigba n ta ti alawo ko ni, ati pe ko si ohun ti a n fi ede Oyinbo se ti Yoruba naa ko se se se daadaa.
Laipe yii naa, Obasa soro to wuni lori nipa Ose Yoruba ti Ijoba Ipinle Eko fe se.
Ni bayii, IROYIN OWURO dara po mo awon ti won n ba Obasa yo ayo ojo ibi re.
Adura wa ni pe ki Olorun tubo maa fun ni emi gigun, alaafia to peye, ogbon, imo ati oye lati tubo maa dari awon asofin si ii rere, to maa mu idagbasoke ba Ipinle Eko.