Akeem Lasisi
– E ka nipa igbesi aye oludasile Globacom ati eko pataki to ko wa
–
Idunnu n subu lu ayo ninu ile gbajugbaja onise okowo to tun je olowo tabua, Dokita Mike Adenuga, tori pe o ti pe eni odun kan din laadorin – 69 years bayii.
Dokita Adenuga je akanda eda to da ile ise Globacom sile, nibi ti opo eniyan ti n sise, to si je pe ile ise naa n se daadaa fun oro aje Naijiria.
Adenuga lo tun ni ile ise Con Oil ati awon okowo nla nla miiran.
Oun ni eni ti Olorun da lola latari bi o se tepa mose lati ibere pepe, to si je pe o ti figba kan gbe ilu oyinbo, ko to dari wale.
Kii se eni kan to maa n fa ijongbon tori pe o ni owo.
Bee, kii maa n se lau-lau kaakiri.
Opo eniyan naa lo mo pe Adenuga kii kuku se ilumomika to maa n be kaakiri, debi wi pe sasa ni apejo tabi aseye ti a ti maa n ri I .
Sugbon bi ko tie jade, owo re n jade, to si n tan kaakiri, to fi n se aye lore.
Idi niyi to fi je pe ile ise Globacom maa n nawo lati mu idagbasoke ba ilu, eyi ti awon oloyinbo n pe ni Corporate Social Responsibility, iyen CSR.
Bi apeere, Globacom maa n se iranwo fun awon amuludun bi olorin, onifiimu ati awon alawada komei.
Bakan naa, o ya awon kan laarin won ti won maa n pe ni Glo Ambassadors, ti won maa n se asoju ile ise naa nibi gbogbo.
Owo nla nla ni Adenuga maa n fun won.
Lara iru awon bee ni King Sunny Ade, Ebenezer Obey, D’Banj, Funke Akindele, Odunlade Adekola, PSquare ati alwada Gordons.
Bakan naa, Globacom maa n se akitiyan lori igbende asa ati ise wa.
Idi niyii ti o fi maa n gbaruku ti Ojude Oba ati Ofala Festival ti awon Igbo.
Iroyin fi ye wa pe Alagba Adenuga maa n gbaruku ti awon oba alaye, paapaa kakiri ile Yoruba.
Bakan naa, won ni o je eni kan to maa n fi emi imoore han upo
Idi niyii to fi je pe ojobii re maa n je eyi ti opo eniyan maa n fi okan si, ti won si maa n se adura fun un.
Idi niyii ti IROYIN OWURO naa fi karamasiki ojo eye naa, ti a si n gba a ni adura pe ki Olorun Oba tbo maa gbe e ga, ko si maa daabo bo emi re.
O dun, oo, o pe, won ni Oluwa lo n fun ni.
Ki Edumare tubo maa fi meteeta se Dokita Mike Adenuga lore o.
MMMMMMMMMMMMMMMMMMMMMMMM
Eni Olorun da: ITAN IGBESI AYE DOKITA MIKE ADENUGA
A bi oloye Michael Adeniyi Agbolade Ishola Adenuga ni ojo kokandinlogbon osu kerin, odun 1953.
Baba to bii lomo, Oloogbe Michael Agbolade Adenuga, ni o je agba olukoni nigba aye re, nigba ti iya re, Omoba Juliana Oyindamola Adenuga, ti oruko re maa n je Juliana Oyindamola Onoshile tele je onisowo pataki ni igba aye re.
Ibadan Grammar School, ni ilu Ibadan, ni olowo tabua ti opo eniyan mo si THE BULL gbe kekoo, ti o si tun lo si Comprehensive High School Ayetoro fun ipele ti won n pe ni Higher School Certificate.
Oro Adenuga je mo kadara, nitori pe eni ti o wa di olola, oloro pataki yii naa ti la isoro koja.
Bi apeere, o ti wa moto tasin (taxi) ri ni ilu Oyinbo, lati ri owo fun eko unifasiti ni Northwestern Oklahoma State University.
Pelu aforiti ati ipinnu pe oun maa je eniyan gidi laye, o tun ra pala lo si Pace University ni ilu New York, bakan naa ni orile-ede Amerika, nibi to ti gba oye imo isowo, Business Administration.
Oro Adenuga wa ja si pe, lopo igba, eni ti ko se bi alaaru l’Oyingbo, ko le se bi Adegboro l’Oja Oba.
Sugbon bawo ni Adenuga se bere si lowo gan-an?
Opo eniyan ko mo pe ibi isowo alabode ni akanda Edumare naa ti bere owo nini.
Ni odun 1979 lo ti koko di eni to n ni owo milionu, nigba to n ta aso leesi ati oti elerindodo ti a n pe ni minerals. Eni odun mokandinlogbon (29 years) nii se nigba naa.
Ti a ba wa gba awon elomiran nimoran pe ki won se karakata, paapaa awon to lo si yunifasiti, oro le ma tete ye won tori ise ti won a ti maa wo kootu, ti won a fun okun mourn ni o maa je won logun.
Ni odun 1990 ni irawo Michael Adenuga ri apere ati gboregejige, nigba ti o gba iwe ase lati maa wa epo. Leyin odun kan, ile ise iwapo re to n je Consolidated Oil ri epo ni Ipinle Ondo, to si je ile ise epo ti Naijiria to je akoko lati se iru aseyori bee.
Ohun ti eyi tun n fi ye wa ni pe ko ye ki eniyan maa duro soju kan yala lenu ise oba ni tabi nidii isowo.
Bakan naa, oruko ile ise Adenuga to n je Consolidated Oil lo jo pe o bi oruko ti awon ile ita epo betiro re, iye Con Oil, ti jade.
Igba to tun di odun 1991 ti foonu GSM de, Adenuga ko tun sun asungbagbe.
O woye pe ojo iwaju ibanisoro alagbeeka yoo dara.
Pelu ireti ati ikiya lo tun se gbe owo nla jade, to si dije fun iwe ase lanseesi.
Adenuga koko ri ikuna nigba ti ijoba Obasanjo to bere GSM gbegi le eto tita ati rira lanseesi naa, ti o si gbe Adenuga lowo lo.
Sugbon nigba ti ko tori eyi sa kuro nibi ti ireti re wa, nigba to di odun 2003, o ri lanseesi Globacom gba, to si je pe, lonii, ile ise naa lo je eyi to laami-laaka sikeji.
Adenuga sin i lati bere sii sowo, to si je pe, di oni olonii, idan n lo lorita meta ni.
Awon eniyan kan beru nigba kan pe eniyan dudu ko le da se eto ile ise ero ibanisoro, tori awon bii oyinbo ati awon to wa lati orile ede miiran ti idagbasoke ti wa lo wa nidii awon ie ise miiran.
Sugbon sa, Adenuga ti fihan pe ko si ohun ti igun se ti obo ko se, to si je pe o ti re egun naa danu lori omo Naijiria ati Afirika.
Ko wa jo ni loju pe opo oye ni won ti fi da olola wa naa lola.
African Entrepreneur of The Year at the first African Telecoms Awards (ATA) in August 2007.
Grand Commander of the Order of the Niger
Otunba Apesin of the Ijebu clan
Commander of the Legion of Honour by President Emmanuel Macron of France.[18]
Top 100 most influential Africans, by New African magazine.
mmmmmmmmmmmmmmmmmm
ORIKI AWON IJEBU
Ijebu omo alare,
Omo Alare, Omo epe o ja
Omo arojo joye,
Omo alagemo ogun woyowoyo,
Omo aladiye ogogomoga,
Omo adiye balokun omilili,
Ara orokun, ara o radiye,
Omo ohun seni oyoyonyo,
Oyoyo mayomo ohun seni olepani,
Omo dudu ile komobe se njosi,
Pupa tomo be se okuku sinle,
Omo moreye mamaroko, morokotan eye matilo, Omo moni isu nle ma ma lobe, Obe tin benile ko mo ile baba to bi wan lomo,
Omo onigbo ma’de,
Omo onigbo mawo mawo,
Omo onigbo ajoji magbodowo,
Ajoji tobawo gboro yio di ebora ile baba tobi wan lomo.
Ijebu omo ere niwa,
Omo olowo isembaye, towo kuji to dode,
Ko to dowo eru, koto dowo omo.
Orisa je n dabi onile yi,
Niwan fi n pe igba ijebu owo,
Kelebe ijebu owo,
Ito ijebu owo, Dudu ijebu owo,
Pupa ijebu owo,
Kekere ijebu owo,
Agba ijebu owo.
Ijebu ode ijebu ni,
Ijebu igbo ijebu ni,
Ijebu isara ijebu ni,
Ayepe ijebu, Ikorodu ijebu ijebu noni
Ijebu Omo Oni Ile nla,
Ijebu Omo Alaso nla!
Ajuwaase ooo