Ìyá mi, ìyá mi (Ekun Iyawo)

Cover of Ekun Iyawo book.

Òkóńkòkó ni mí o
Tí mo kósùpá r’Òṣogbo
Tí mo w’ẹ̀wù oyè r’Ọbaàgùn
Orí tí ó d’olóyè kìí fẹ́
Orí mi ó d’olóyè bó dọ̀la
Ire lónìí, orí mi àfi’re

Mọ̀mọ́ mi, mọ̀mọ́ mi
Mọ̀mọ́, mo ní n wá gba’re tèmí kí n tó máa lọ
Ire tèmi ò mọ̀mọ̀ pọ̀
Ire mi ò mà kún wọ́
Ire ẹja lómi ló kúkú mọ
Ire kọ̀ǹkọ̀ lódò ló mà wà
Ire ọmọ bíbí inú ìyá o
Ìlúmọ̀mí bí ò tó mi lẹ́rù n ò lọ o
Ire lónìí, orí mi àfi’re

Bùlenge, bùlenge
Bùgé bùgé àkàrà
Mo ní ò ṣe lẹ́yìn erèé
Bùlenge ọmọ ń bẹ lọ́wọ́ yeye
Mọ̀mọ́ tí mo mú s’àkọ́bí o
Mọ̀mọ́ mi fún mi ní bùgé-bùgé ṣe
Ire lónìí, orí mi àfi’re

Ìyá mi, ìyá mi
Ewé mẹ́ta lè bá bá n já
Ẹ̀ bá bá n jáwé pẹ́pẹ́ kí n pẹ́ láyé
Ẹ̀ bá bá n jáwé tẹ̀tẹ̀ n tẹ̀’lú jìnnà
Ẹ̀ bá bá mi já’wé olúyèré o
Olúyèré, k’ọ́mọ ó yè lẹ́yìn mi o
Ire lónìí, orí mi àfi’re

Ads

A ti ṣe é mọ’lé olórogún ṣe?
À á tii ṣe e mọ̀’wà àgbàá hù lọ́ọ̀dẹ̀?
Bí wọ́n rán’ni ní’ṣẹ́, wọ́n ní tè’we làá kọ́ jẹ́
Àgbà tí ò bínú lọmọ rẹ̀ ẹ pọ̀ sí o
Ire lónìí, orí mi àfi’re.

(From EKUN IYAWO: The Bride’s Poetry by Akeem Lasisi. Request a copy via lasaisai@yahoo.com and watch full EKUN IYAWO video, featuring Kabirah Kafidipe below; then, see more videos on Akeem Lasisi & the Songbirds on YouTube.)